These songs were collected from Hameed Nasiru Akinlade of Akinlade Cultural Group after the group's performance at Ede Mapo Arogun Day (Ede annual festival held on 30 November 2013).
Ẹdẹ Màpó Àrógun, Ìlú ńlá
Ẹdẹ Màpó Àrógun, Ìyàkùn àgbò
Ẹdẹ Màpó Àrógun ìlú Tìmì
Ìlú tí a mọ̀ fún sùúrù tí kìí ṣagídí
Ìlú ti a mọ̀ nílùú ẹ̀sìn, a dúró déédé,
Mùsùlùmí ìlú Ẹdẹ kéwú wọ́n tún ńkírun
Onígbàgbọ́ ìlú Ẹdẹ wọ́n dòpó Jésù mú
Ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ ńṣe tiwọn láì díra lọ́wọ́
Sẹri pé Àgbàlé gbajúmọ̀, ó ní láárí
Àgbàlé gbajúmọ̀, a ma ntoto
Àgbàlé gbajúmọ̀ ó mohun tó yẹ
Tìmì Àgbàlé àkọ́kọ́ tán j’ásíwajú Ẹdẹ
Ipa rere tán fi lélẹ̀ kò ti ẹ̀ parẹ́
Tìmì ò dédé j'ọba l’Ẹ́dẹ, ẹ tẹ́tí ẹ gbọ́
Ọ̀rọ̀ ló se bí ọ̀rọ̀, ẹ síwèé ìtàn wò
Àwọ̀n jàgùdà ọlọ́sà ní ń yọ Ẹdẹ lẹ́nu
Wọ́n jíwa léwúrẹ́ kó, wọ́n ńkó wa nírúgbìn lọ
Wọ́n ń pawá lọ́mọ, wọn tún fẹ wa láya
Òkìkí kàn délùú Ọ̀yọ̀ ní bi t’Ólúkòso ti ń jọba
B’Ólúkòso ti gbọ́rọ̀ yìí ló bá fárígá, n ló bá bínú
Ìbínú yìí pọ̀ púpọ̀jù tó fi jẹ́ wípé
Lalala bùlà bùlà bùlà bùlà niná ń yọ lẹ́nu Ólúkòso
Wéré wéré wàrà ǹsàsà lọbá bá ránṣé sí Tìmì
Kówá lọ gbàwọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ ọlọ́sà ìlú Ẹdẹ
Akíkanjú ni Tìmì tẹ́lẹ̀ jagun jagun tún ni
Ó ti rogun láìmọye
ìgbà tó darí wálé láì farapa
Tìmì Àgbàlé Ọlọ́fà Iná
Tìmì Àgbàlé Ọlọ́fà ìjà, akíkanjú lógun
Aláyà bí àrà ni Tìmì Àgbà
Jagun jagun l’Àgbàlé a wí fún ni kó tó dáni
Ó fojú ọlọ́sà rí màbo nígboro Ẹdẹ
Ó sewọ́n kása kàsa, ó tún sewón kàsà kàsà
Ó fọfà iná se kísà
fúnwọn ní wọn bá sálọ
Ọ̀pá kan soso mà ni Tìmì òò
Ọ̀pá kan soso tí ńdagba mààlúù
nígbó
Kò fólè kò fọ́le ló jẹ́ kó láwọn ọlạ́sà lugbó
Iná pẹ̀lú ẹ̀tù wọn ò
lè gbé káriwo má sọ
Ààyá pẹ̀lú ẹ̀tù wọn ò
lè gbé káriwo má sọ
Aáyán pẹ̀lú adìyẹ wọn ò lè bárawọn gbé
Kẹ́nìkan má finú ilé sílẹ̀ fún ẹnìkan
Ìgbà tí a lé ọlọ́sà lọ tan nìlú Ẹdẹ rójú
Ìgbà yí la tó mọ̀pé Tìmì ò rorò
Oní fàájì ni Tìmì bóbá dọjọ́ àrìyá, Ẹdẹ kó ni mára
Ẹdẹ ló nìlù ló leré Ẹdẹ lólorin
Ẹdẹ Màpó Àrógun ò kéré níbi fàájì ò.